Lou Hoover
Lou Hoover | |
|---|---|
| Ààrẹ | Herbert Hoover |
| Obìnrin Àkọ́kọ́ Orílè-èdè Amẹ́ríkà | |
| In office 4 March 1929 – 4 March 1933 | |
| Asíwájú | Grace Coolidge |
| Arọ́pò | Eleanor Roosevelt |
| Àwọn àlàyé onítòhún | |
| Ọjọ́ìbí | Lou Henry Oṣù Kẹta 29, 1874 Iowa, Améríkà |
| Aláìsí | January 27, 1944 (ọmọ ọdún 69) |
| Aráàlú | American |
| (Àwọn) olólùfẹ́ | Herbert Hoover |
| Àwọn ọmọ |
|
Lou Henry Hoover (Oṣù Kẹta 29, 1874 – Oṣù Kínní 7, 1944) jẹ́ onínúure ará Amẹ́ríkà, olùṣèwádìí nípa ilẹ̀ ayé, àti Ìyáàfin Àkọ́kọ́ ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti ọdún 1929 sí 1933 gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Ààrẹ Herbert Hoover. Ó jẹ́ olùdarí nínú àwọn àjọ àdúgbò àti àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, títí kan àwọn Girl Scouts of the USA, èyí tí ó ṣe olórí láti ọdún 1922 sí 1925 àti láti ọdún 1935 sí 1937.
Ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní March 29, ọdún 1874, wọ́n bí Lou Henry ní ìpínlẹ̀ Iowa, fún àwọn ti ń ṣé iṣẹ́ báńkì. Ó jẹ́ àkọ́bí àwọn ọmọbìnrin méjì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré ìdárayá, títí kan baseball, bọ́ọ̀lù, àti ọfà, ó sì kọ́ àwọn iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì mìíràn.
Lẹ́yìn tí Henry parí ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́dún 1893, ó ríṣẹ́ ní báńkì bàbá rẹ̀. Ó lọ sí Yunifásítì Stanford láti gba ẹ̀dà ìjùmọ̀sọ̀nà nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ibẹ̀ ni ó ti pàdé ọkọ rẹ̀ tí yóò di ọjọ́ iwájú, Herbert Hoover, ẹni tí ó ti dàgbà jù, ọ̀rẹ́ wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀. Ó tẹ̀síwájú nínú ìfẹ́ rẹ̀ sí eré ìdárayá nígbà tí ó wà ní Stanford, ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Stanford Women's Athletic Club ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀. Ní ọdún 1898, Hoover di obìnrin àkọ́kọ́ tí ó gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ayé láti Stanford.[1]
Ìgbéyàwó àti iṣẹ́ òṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 1899, wọ́n sì kọ́kọ́ gbé ní China; ìṣọ̀tẹ̀ kan bẹ̀rẹ̀ ní ọdún náà, wọ́n sì rí ara wọn láàárín ogun.
Ní ọdún 1901, wọ́n kó lọ sí ìlú London, níbi tí Hoover ti tọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì dàgbà, ó sì di àlejò tó gbajúmọ̀ láàárín àwọn arìnrìn-àjò kárí ayé.
Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọn ṣé aṣíwájú àwọn ìsapá ìrànlọ́wọ́ láti ran àwọn asásálà ogun lọ́wọ́. Ìdílé náà kó lọ sí Washington, D.C. ní ọdún 1917, nígbà tí wọ́n yan Herbert gẹ́gẹ́ bí olùdarí fún Food and Drug Administration, Lou sì di olùgbèjà ààbò oúnjẹ tí ó ń ṣé àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ rẹ̀.[2]
Lou le sọ èdè márùn-ún, pàápàá jù lẹ́yìn tí ó ti gbé ní China àti Europe.
Gẹ́gẹ́ bí Ìyáàfin Àkọ́kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Hoover di obìnrin àkọ́kọ́ ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tí wọ́n fi ọkọ rẹ̀ sí ipò ààrẹ ní ọdún 1929. Ìpè Jessie De Priest sí Ilé Ààrẹ fún tíì jẹ́ àríyànjiyàn fún ìtìlẹ́yìn rẹ̀ fún ìṣọ̀kan ẹ̀yà àti ẹ̀tọ́ aráàlú.
Ó kọ̀ láti fún àwọn oníròyìn ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, ṣùgbọ́n òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó máa ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí rédíò déédéé. Hoover ló ṣe àtúnṣe Ilé Ààrẹ nígbà tí ó wà nípò, ó sì tún ṣe àkóso kíkọ́ ilé ààrẹ ní Camp Rapidan.[3]
Orúkọ Hoover bàjẹ́ pẹ̀lú ti ọkọ rẹ̀ nígbà Great Depression. Àwọn ènìyàn àti àwọn tó sún mọ́ ọn kò mọ̀ nípa iṣẹ́ àánú tó ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn aláìní nígbà tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyáàfin, nítorí ó gbàgbọ́ pé ìpolówó ìwà ọ̀làwọ́ kò dára.
Lẹ́yìn tí Herbert parí ìpolongo àtúndìbò rẹ̀ ní ọdún 1932, wọ́n padà sí California, wọ́n sì kó lọ sí ìlú New York ní ọdún 1940. Hoover bínú gidi nípa ikú ọkọ rẹ̀, ó fi ẹ̀sùn àìṣòótọ́ àti ọ̀nà ẹ̀tàn kan án, ó sì tako ìṣàkóso Roosevelt gidi.
Ikú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lẹ́yìn tí wọ́n fi Ilé Ààrẹ sílẹ̀, ó ṣiṣẹ́ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún ọkọ rẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Hoover kú nítorí àrùn ọkàn ní ọjọ́ keje oṣù kìíní ọdún 1944, nígbà tí ó wà ní New York. Ọkọ rẹ̀ rí i nígbà tí ó padà sí yàrá wọn.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "First Lady Biography: Lou Hoover". National First Ladies' Library. Archived from the original on October 7, 2022. Retrieved October 14, 2022.
- ↑ "Virtual Presentation – "A Woman of Achievement: Stories from the Life of Lou Henry Hoover," March 18". River Cities' Reader (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). March 9, 2021. Retrieved July 6, 2023.
- 1 2 "2019.001.022 [Sculpture] | Teaching Iowa History". teachingiowahistory.org. Retrieved 2024-04-04.
Ìwé kíkà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Allen, Anne Beiser (2000). An Independent Woman: The Life of Lou Henry Hoover. Greenwood Press. ISBN 978-0-313-31466-7. https://archive.org/details/independentwoman00all_zg2/.
- Anthony, Carl Sferrazza (1990). First Ladies: The Saga of the Presidents' Wives and Their Power, 1789–1961. William Morrow and Company. ISBN 978-0-688-11272-1. https://archive.org/details/firstladiessagao00anth.
- Boller, Paul F. Jr. (1988). Presidential Wives. Oxford University Press. pp. 270–283. ISBN 978-0-19-503763-0. https://archive.org/details/presidentialwive0000boll/.
- Caroli, Betty Boyd (2010) (in en). First Ladies: From Martha Washington to Michelle Obama. Oxford University Press, USA. pp. 176–188. ISBN 978-0-19-539285-2. https://archive.org/details/firstladiesfromm0000caro.
- Jeansonne, Glen; Luhrssen, David (2016) (in en). Herbert Hoover: A Life. Penguin. ISBN 978-1-101-99100-8. https://books.google.com/books?id=9uD4DAAAQBAJ&q=lou.
- Pryor, Helen (1969). Lou Henry Hoover: Gallant First Lady. Dodd, Mead. ISBN 978-0-396-05992-9. https://archive.org/details/louhenryhooverga00pryo.
- Walch, Timothy, ed (2003). Uncommon Americans: The Lives and Legacies of Herbert and Lou Henry Hoover. Bloomsbury Academic. ISBN 978-0-275979-96-6.