Batile Alake
| Batile Alake | |
|---|---|
| Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Batili Alake |
| Ọjọ́ìbí | Ijebu Igbo , Ogun State , Nigeria |
| Aláìsí | Àdàkọ:Ojó Iku |
| Irú orin | Waka |
| Occupation(s) | Akọrin |
| Instruments | Orin |
| Years active | 1950s–1980s |
Batile or Batili Alake
Listen (died 2013) was a prominent Yoruba waka singer.[1][2]
Batile Alake je olorin ara Naijiria. Omo bibi ilu Ìjẹ̀bú-Igbó Ni Ipinle Ogun. Alhaja Batile Alake kú ní ọdún 2013 ni ọmọ ọdún méjídínlọ́gọ́rin,[3] ti ao sì mọ dédé Ojó orí re.[4]
Iṣẹ́ Owó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Alake ló so orin Yọrùbá to ni imisi nínú ẹ̀sìn Islam di gbajugbaja bí ó ti jẹ́ pé ó mọ kò ní àwọn àyè ayẹyẹ káàkiri gbogbo ilé Yorùbá ti ó sì tún jẹ́ àkókò olorin Waka tí yíò se àwo orin jáde. Ipa àti iṣẹ́ orin kíko rẹ jẹ mú sán mú san ni àwọn àkókò 1950 sì 1960. Ó wá lára àwọn olorisirisi olórin obìnrin tí ó gbajúmọ̀ ju nínú àwọn tí wọ́n ńkó orin Waka Láàrin àwọn Odún 1950 si 1960. Lara won tí àti rí, Olawunmi Adetoun, Decency Oladunni, Adebukola Ajao Oru, Foyeke 'Ajangila' Ayoka, Ayinke Elebolo, Aduke Ehinfunjowo, Hairat Isawu, Salawa Abeni, áti Adijat Alaraagbo.
Ìsowó kò orin re je títí orin Rárà, èyí ti ó jẹ́ ọ̀na orin kíko kan tí ó wọ́pọ̀ láàrin àwọn obìnrin Yorùbá gẹgẹbi àṣà wọn. Pelu orin, ìlù àti àwọn Elégbè, Alake àti àwọn akọrin Waka yókù yí Ọ̀nà tí wọ́n gba kò orin Waka padà sí ti èyí tí ó ṣe sọ di ọwọ tí wọ́n ń sì lọ ànfàní tí ilé ìgbóùn sílè tuntun tí o sese de, tí wọ́n fi ṣe àwon àwo orin jáde. Botilejepe òpó ènìyàn ni wọn mon bù oriyin orin Waka fun Salawa Abeni látàrí Ọ̀nà ara ti o gbe wo inú kiko orin Waka, ṣùgbọ́n Alake dúró ṣinṣin lókè téńté.
Nítorí pé orin rárá kiko sì jẹ́ oun ti ó gbajúmọ̀ ní àkókò èwe Alake, ó fún ní àǹfààní tí àwọn akegbé rẹ yoku ó ní, lèyí tí ó fi ara hàn nínú àwọn ìjìnlè ọ̀rọ̀ àti èdè tí òun mon nlo nínú orin re. Bí ó ṣe ń yọ èdè be ni òun pàrò àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá rí pe ní yíò tún bò bù iyì àti ẹwà kún orin re. Èyí fi ara hon púpò nínú bí kò ṣe bẹ̀rù láti mú àwọn èdè àti òrò tí kì ṣe Yorùbá bonú orin re,leyi tí ó tún bò bù iyì àti àgbéga kún ìṣe orin re.
Látàrí bí ilakaka rẹ sínú òwò orin ṣe jẹ́ lọ́wọ́ ni àwọn nkan bí ọdún 1970,o tẹ̀síwájú pelu ìgbéjáde àwọn orin kan tí a lè pè ní orin oríkì afé, tí ó kó fún àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí wọ́n ṣe ìrànlówó àti àtìlẹ́yìn fún. Àmọ́ eleyi kò jẹ apileko fún orin re, nígbà tí ó di bí àwọn ọdún 1980, ó tún yí apá ọ̀nà orin re pada pelu bí ó ṣe fi ọ̀rọ̀ orin onípele meta kún ọ̀nà àágbà kò orin re lèyí tí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fẹ́ràn láti mọ jọ sí orin fẹ́ràn.
| Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Bianchi, Ugo (1994). The notion of "religion" in comparative research: selected proceedings of. L'ERMA di BRETSCHNEIDER. pp. 181. ISBN 88-7062-852-3. https://books.google.com/books?id=4AKV1PK8bxcC&pg=PA181.
- ↑ Shepherd, John; Dave Laing (1994). Continuum encyclopedia of popular music of the world, Volumes 3-7. Continuum. pp. 165. ISBN 0-8264-7436-5. https://books.google.com/books?id=xjLaAAAAMAAJ.
- ↑ https://en.wikipedia.org/wiki/Batile_Alake#cite_note-Waka-3
- ↑ https://en.wikipedia.org/wiki/Batile_Alake#cite_note-4